Getting your Trinity Audio player ready...
|
L’aipe yi, ìjọba àpapọ̀ polongo pé wọ́n yoo bẹrẹ sii ṣe idanilẹkọ àwọn ọmọ orileede Naijiria l’ori àwọn ewu ati ìjàmba to wọpọ ni ìgbà òjò ati ìgbésẹ̀ ti ara ìlú ni láti gbe ki wọn le wa ni ailewu ẹ̀kún omi.
Ṣaaju àsìkò yii, Minisita àwọn nnkan alumọni inu omi ati ìmọ́tótó, Joseph Ustev kéde pe àwọn agbègbè to le ni egberun kan ló wa ninu ewu àgbàrá òjò, kaakiri ọgọrun ìjọba ibile to wa ni ipinle metalelogbon. àwọn wonyi ni àgbàrá ojo ma da laamu gidi gan. Ni ida keji, agbègbè egberun meji o le die kaakiri ìjọba ibile igba le laadorun le fori lugbadi àgbàrá ojo ferefe.
Àwọn ipinle to wa ninu ewu àgbàrá ojo ni ipinle Abia, Abia, Adamawa, Akwa Ibom, Anambra, Bauchi, Bayelsa, Benue, Borno, Cross River, Delta, Ebonyi, Edo, Gombe Imo, Jigawa, Kebbi, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger, Ogun, Ondo, Osun, Oyo, Rivers, Sokoto, Taraba, Yobe, Zamfara, ipinle Eko ati olu ìlú Naijiria.
Koda àjọ to n mojuto ọrọ oju ọjọ lorilẹede Naijiria, NIMet se ikilọ pe ojo arọrọda yoo waye loṣu karun ati ikẹfa odun yii lorilẹede Naijiria.
Ti àgbàrá ojo ba bere sii da agbègbè kan laamu, o maa n mu ikolu ba emi, dukia ati oun ọ̀sìn to wa níbẹ̀.
Ni odun to koja, eniyan milionu kan o le loodunrun ni àgbàrá ojo sakoba fun, koda àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rin eniyan lo padanu ile ti won gbe, nigba ti oodunrun eniyan jade kuro laye.
Eyi lo faa ti Dubawa se se akosile yii ki a le da ara ìlú leko
Àwọn oun ti o ni lati ṣe l’àsìkò òjò
Mo agbègbè re daaada ki o si mo àwọn ibi ti o le sare si ti ẹ̀kún omi ba bere.
Ma se rin tabi wa ọkọ̀ wọ inu àgbàrá ojo biotilewu ki o kere mọ: O seese ki àgbàrá ojo to le ni iwon bata ese kan wọ ọkọ̀ kuro loju popo, o si se se ki o gbe eniyan lọ. Imoran àwọn onimo ni pe ki onitoun duro ki ojo daa ki àgbàrá si wo lo ki won to tesiwaju.
Fi etí sílẹ̀ fun ojúlówó ìròyìn nipa ojú ọjọ́ ki o to fi ilé tàbí ibi òwò rẹ sílẹ̀: ni ọpọlọpọ igba, eniyan le ti kuro ni ile tabi ibi ise ki ojo to bere, ẹẹ̀kún omi le ti korajo ni ọna, o se pataki ki a fi eti sile fun ifilo nipa àwọn agbègbè wonyi ki a le yera. Ninu oro minisita Ustev, o salaye pe fun odun 2025, ifilo nipa ẹ̀kún omi ma se àfojúsùn agbègbè kọọkan ki awon olugbe ibe le gbaradi.
Ma se da ile si oju popo tabi àgbàrá, eyi le mu ki ẹ̀kún omi buru si. Jowo, lo àwọn kole kodoti ti ìjọba ti pese fun araalu.