Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àhesọ: Àwọn ọkùnrin Làìbéríà ti wà lára àwọn mẹ́ta tí ó kéré jùlọ ní’le adúláwọ̀, àti ìdá mẹ́tàlélógún kárí ayé.
Àbájádí: Ìwádìí fi hàn pé àwọn ọkùnrin Làìbéríà wà lára àwọn tó kúrú jù lọ kárí ayé. Àyẹ̀wò ọdún 2020 kan tí NCD Risk Factor Collaboration ṣàkóso àti iṣẹ́ àkànṣe kan tí Imperial College London ṣe àtìlẹ́yìn fún, ṣe àtìlẹ́yìn fún ọ̀rọ̀ náà.
Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Láìpẹ́ yìí, Diamond Online, aṣàmúlò ẹ̀rọ ayélujára Facebook, gbé ìròyìn kan tí ó tọ́ka sí pé àwọn ọkùnrin Làìbéríà ni wọ́n ti gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta tí ó kúrú jùlọ ní Áfíríkà. Ìkànnì ayélujára náà fi kún un pé àwọn ọkùnrin Làìbéríà náà ní ipò mẹ́tàlélógún tí ó ga jùlọ láàrin àwọn ènìyàn kéékèèké kárí ayé.
Àtẹ̀jíṣẹ́ náà lo àwòrán ènìyàn méjì – àgbàlagbà ọkùnrin kan àti ọ̀dọ́ kúkúrú kan. Ẹni tí ó gbẹ̀yìn ni Alexander Cummings, ẹni tí ó kópa nínú ìdìbò ààrẹ 2023 ní Liberia.
Kò sí àrídájú ìdí tí wọ́n fi lo àwọn àwòrán Ọ̀gbẹ́ni Cummings, ẹni tí ó tún jẹ́ aláṣẹ Coca-Cola tẹ́lẹ̀rí, láti sọ ìtàn náà.
Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú irúfẹ́ ẹ̀sùn náà, èyí tí ó wà ní ààlà gíga àwọn ọkùnrin Làìbéríà, DUBAWA pinnu láti ṣàyẹ̀wò àhesọ náà.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Ìwádìí kan tí Business Insider tẹ̀ jáde ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹfà, ọdún 2023, rí i pé orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ló ní àpapọ̀ ènìyàn tó kéré jù. Àwọn wọ̀nyí ni:
- East Timor
- Laos
- Madagascar
- Guatemala
- Philippines
- Nepal
- Yemen
- Marshall Islands
- Bangladesh
- Cambodia
- Indonesia
- Malawi
- Rwanda
- India
- Vietnam
- Perú
- Papua
- Solomon Island
- Mozambique
- Bhutan
- Brunei
- Myanmar
- Liberia
- Honduras
- Sri Lanka.
Mẹ́rìnlá wá láti Asia nínú wọn, márùn láti Áfíríkà, mẹ́ta ní Central àti South America, méjì ní Pacific, àti ọ̀kan ni Àárín Ìlà Oòrùn.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀ náà ṣe sọ, Làìbéríà jókòó ní ipò kẹtàlélógún kárí ayé àti nọ́mbà kẹta ní Adúláwọ̀.
“Ọmọ orílẹ̀-èdè Làìbéríà má ń ga ní ìwọn ẹsẹ bàtà márùn at íǹṣì 2.85. Ọkùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Làìbéríà kan le ga ní ìwọ̀n ẹsẹ bàtà márùń ati íǹṣì 4.43,” ni ìròyìn náà sọ. Ó fi kún pé, “ T’obìnrin orílẹ̀-èdè Làìbéríà jẹ́ ìwọn ẹsẹ bàtà márùn àti íǹṣì 1.28 ni gíga.”
Àkójọpọ̀ ọdún 2020 tí NCD Risk Factor Collaboration ṣàkóso àti iṣẹ́ àkànṣe kan tí ó so mọ́ Imperial College London, tọ́ka sí oúnjẹ gẹ́gẹ́ bi ìṣokùnfà ìdàgbàsókè segesege.
Ìwádìí síwájú sí i lórí ìwọ̀n gíga àwọn ọkùnrin ní oríṣiríṣi kọ́ntínẹ́ntì fi àlàfo hàn. Fún àpẹẹrẹ, ní Áfíríkà, àpapọ̀ gíga fún ọkùnrin kan ní sẹntímítà jẹ 172; ní Asia, 167.5; ní Europe, 180; ni North America, 175; àti ní South America, 171. Àwọn àpapọ̀ wọ̀nyí, nígbà tí a bá fi wé ọkùnrin Làìbéríà, ní ìyàtọ̀ díẹ̀.
Kárí ayé, ètò mẹ́tíríkì ní a fi ń wọn bí ǹkan ṣe ga tó. Síbẹ̀síbẹ̀, ní ọdún 2024, ìwádìí fi hàn pé orílẹ̀-èdè mẹ́ta-Liberia, Myanmar, àti Amẹ́ríkà ṣì ń tẹ̀síwájú nínú ìdọ́gba wọn fún irú ìwọ̀n bẹ́ẹ̀.
Àkótán
Pẹ̀lú àwọn ìwádìí tí a rí, ó tọ́ láti sọ pé òtítọ ni àhesọ náà.
Varney Dukuly ni ó kọ́kọ́ ṣe àkọsílẹ ìwádìí yìí lé’dè gẹ̀ẹ́sì, tí Sunday Awóṣòro sì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Yorùbá.