YorubaExplainersHealth

Oun tí o ní láti mọ̀ nípa ààrùn aṣekupani Mpox

Getting your Trinity Audio player ready...

Àkòrí ọrọ   

Lọwọlọwọ yii, ìlọsókè ààrùn mpox ń da orile-ede Nàìjíríà láàmú. Ara ẹranko ni wọn ti ma n ko aarun yii si ara èèyàn, to si n tàn ka láàrin àwùjọ ènìyàn.

Àjọ to n rísí ọrọ ìlera lágbayé, WHO pẹlu àjọ to n risi ìdènà ààrùn ni ilẹ̀ Áfríkà tí kéde pé ìtànkálẹ̀ ààrùn mpox jẹ ìjàmbá nla fún ètò ìlera láwùjọ, o sì se pàtàkì kí won tètè dẹkun rẹ̀.

Lẹyìn ọdún 1970, ààrùn mpox ṣẹ́yọ ní ilà oòrùn, iwọ oòrun ati aringbungbun ilẹ̀ Áfríkà. Ní ọdún 2003, ààrùn náà bẹ sílẹ ní orile-ede Améríkà, awọn oniwadii fi idi re mu’le pe èyí ti ara ẹran ìgbẹ́ wá. Láti odún 2005, ọgọọrọ ènìyàn ló n f’orílugbadi ààrùn yíì ní orile-ede Congo lọdọọdun. Ni ọdun 2017, aarun mpox bẹ́ sí’lẹ̀ ní orile-ede Nàìjíríà, o sì bẹrẹ síí tan ka àwọn agbègbè to sunmọ, latari awọn arinrin-ajo ti wọn kuro ni ileto kan sì òmíràn. 

Oríṣi aarun 

Irúfẹ́ ààrùn mpox méjì ló wà, èyí ti a mọ sí clade I ati clade II.

Clade I yìí buru ju, o sì máa n fa àárẹ̀ d’ojú ikú. Ìtànkálẹ̀ mpox ti pa ipin mẹwa awọn ènìyàn tó fori lugbadi ààrùn yíì, ṣugbọn awon onisegun ti n ri ojutu sì onírú àisàn mpox yíì. Èyí lọ wopo julo ní aringbungbun ile Afrika. Ẹyà àisàn Clade II lo be sílẹ ni ọdun 2022 to sì tanka awon orílè-èdè agbaye. Èyí wọpọ ni iwọ oorun ilu Áfríkà. 

Ìtànkálẹ̀ ààrùn 

Èèyàn lè kọ aarun mpox lati ara èèyàn mii to ba ni aisan naa, yala nipasẹ itọ́, éwo, kẹlẹbẹ, tabi awon omira kọọkan lati ará aláìsàn bóyá lati inú iho idi tàbí oju ará aláìsàn. Ìkókó lè fara kasa aarun yi ti ìyá rẹ bá ní àisàn yíì. 

Àpẹẹrẹ àti àmì àisàn

Àwọn apẹẹrẹ àisàn yíì máa n farahàn laarin ọsẹ kan, koda eeyan le bẹrẹ síí rí ami àìsàn yíì laarin ojo kan si ọjọ mokanlelogun leyin ti eniyan ba lugbadi aisan naa. Koda, aisan yíì wa lara ènìyàn fún odindi ọsẹ meji sì mẹrin pàápàá ti eya òkí ará onítọ̀ún ò bá jí pépé.

Àpẹẹrẹ aisan to wọpọ ni alefọ, ibà, ọ̀fun dídùn, orí-fífọ́, ki ara maa wu, ẹ̀yìn dídùn, àárẹ̀ ati eegun dídùn. Fún ọpọlọpọ eniyan, alefọ ni ọ ṣáájú.

Àwọn ọmọdé, aláboyún, àti àwon èniyàn ti eya òkí ará wọn ò jí pépé, lè tètè fara kasa àisàn naa.

Ìṣojúùtú àìsàn 

Ó se pàtàkì kí a mọ iyatọ aarun mpox si awọn ààrùn míìrán bii ṣọpọnna ile gbóná, ààrùn measles, àkóràn alamọ, kúrúnà, ìléròrò, atọsi ọlọyun, àti àwon ààrùn ìbálòpọ̀ miran. O ṣeéṣe ki èèyàn tó ti kó ààrùn mpox ní àwọn ààrùn Ìbálòpọ̀ bíi ìléròrò. Kódà, ọmọde tó ní ààrùn mpox lẹ ni ṣọpọnna ile gbóná. Nítorí èyí, o se pàtàkì kí aláìsàn lọ sí ilé ìwòsan fún ayẹwo àti itoju to péye.

Itoju àti abẹrẹ ajẹsara 

Oun tó ṣe pàtàkì ninu itọju ààrùn mpox ni lati dẹkun alefọ, dẹkun ìrora àti lati ríi dájú pé kó burú síi. Nítorí èyí, o se pàtàkì kí èèyàn gbà abẹrẹ ajẹsara mpox kí o má bàá fara kasa aisan yíì. Ẹni to ba fara kàn ènìyàn to ní àisàn mpox gbọdọ gba abẹrẹ ajẹsara laarin ọjọ merinla, ti kò ba ṣi àpẹẹrẹ àisàn. 

Imoran awọn amòye ni ki àwọn ti wọn lè tètè kò aisan naa bíi àwọn ọmọde, aláboyún àti ènìyàn ti eya òkí ará rè ò jí pépé, gba abẹrẹ àjẹsára mpox kí wọ́n ma baa lugbadi aisan naa. O sì se pàtàkì kí a gbé awon ènìyàn to ní àisàn mpox kuro láwùjọ ènìyàn. 

Awon oògùn kọọkan bíi tecovirimat ti wọn fi wo igbona, ni wọn fi n se itoju àisàn mpox biotilejepe ìwádìí n lo lori oògùn miran. 

Ìdènà àisàn 

Aláìsàn ti o bá rí itoju gba, a kuro ni ipò àìsàn laarin ọsẹ kan sì mẹrin. Láti dẹkun ìtànkálẹ̀ àisàn, kí aláìsàn wá ni atimole, kí o sì wọ iboju àti fi aṣọ bò alefọ titi di igba tí yóò jina. Fọ ọwọ́ lóòrèkóòrè pẹlú ọṣẹ àti omi, pàápàá leyin ti o bá fi ọwọ kan egbò.

Àjọ WHO gba imoran pé kì aláìsàn fi omi iyọ̀ fọ egbò to wa nínú enu, joko s’ori omi gbóná ti a fi iyọ̀ sínú rẹ àti lílo òògùn fún irora. 

Akotan

Bí orile-ede Nàìjíríà ṣe n koju ìtànkálẹ̀ ààrùn mpox, o se pàtàkì kí awon ènìyàn mọ nípa aisan yíì àti àwon òun ti wọn fi lé dáàbòbo ará won. Tele ilana ìlera, kí o sì lọ ilé ìwòsan ti o bá ṣe firi ami àìsàn ti a darukọ.

Ìkéde: A ṣe àtúnṣe orúkọ ààrùn “Monkeypox” sí mpox ni ìbámu pẹ̀lú ìlànà àjọ WHO.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button