Fact CheckHealthYoruba

Àtijó ni atẹjade akálékáko nípa igbegi dina oògùn ibà

Ahesọ: Àjọ ilẹ̀ Yúrópù (European Union) ti gbegi dina òògùn mẹ́jìlélógójì ti wọ́n fi ń wo àìsàn ibà.  

Àtijó ni atẹjade akálékáko nípa igbegi dina oògùn ibà

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Ìwádìí wà fihàn pé atẹjade náà wá láti inú ìròyìn kan tí wọn gbé jáde ní ọdún 2017, àti wípé wọn ò lo àwọn oògùn wọ̀nyi fún ìwòsàn ni orilẹ-ede Nàìjíríà.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Ẹ̀fọn ló maá ń fa ibà, àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí fún àwọn ọmọ ènìyàn. Ẹ̀fọn yìí wọpọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀. Botilẹjẹpe àìsàn ibà burú jáì, itọju àìsàn náà wà.

Àjọ tó ń rísí ọ̀rọ̀ ìlera l’ágbayé, WHO ṣ’àlàyé pé àìsàn ibà wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Áfíríkà ju awọn agbègbè míràn lọ.

Láìpẹ́ yìí, àtẹ̀jáde akalekako kan tànká orí ìkànnì ibaraẹnisọrọ WhatsApp pé àjọ ilẹ̀ Yúrópù gbégi dínà àwọn oògùn ibà mẹ́jìlélógójì. Atẹjade náà kìlọ̀ pé kí àwọn ènìyàn má lo òògùn tó ní awon èròjà wọnyi: Plasmotrin, Artequin, Co-arinate, Arco, Artedar, Artecon, and Dailquin.

Àtijó ni atẹjade akálékáko nípa igbegi dina oògùn ibà
Àwòrán atẹjade náà lórí ìkànnì ibaraẹnisọrọ WhatsApp.

Àwọn olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrọ yii ti ṣ’atunpin atẹjade náà láìmọyẹ ìgbà. Wọ́n sì ṣ’atunpin rẹ̀ sí DUBAWA fún ìwádìí. Ìlera ọrọ àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì, a sì lérò pé ó ṣe kókó kí a tètè ṣe ìwádìí lórí irú ahesọ báyìí, ki àwọn ènìyàn lè ṣe oun tó tọ́. 

Ifidiododomule

Itọpinpin kókó ọ̀rọ̀ lórí ayélujára ṣàfihàn ìròyìn nínú iwe ìròyìn Premium Times, Tribune Online, Daily Post ati Daily Trust ni oṣù keje ọdún 2017. Ìròyìn àtijọ́ náà ṣ’alaye pé òògùn ibà mẹ́jìlélógójì ni àjọ ilẹ̀ Yúrópù fagilé.

Kódà, àjọ West Field Development Initiative ṣ’atunpin ahesọ kanna ni oṣù kẹjọ ọdún 2022 pe wọn ṣi n lo òògùn mẹ́jìlélógójì náà fún ìtọ́jú aláìsàn. 

Ilé-isé ìròyìn Premium Times àti Guardian ní ọdún 2017 gbé ìròyìn pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ṣe ìwádìí lórí boya àwọn òògùn náà sí wà lórí igbá. Sùgbọ́n, a kò ri ìwádìí kankan láti ilẹ igbimọ asofin náà.  

Ni ọdún kanna, àjọ ti o n mojuto oògùn, oúnjẹ ati ohun mímu nílẹ̀ wa, NAFDAC ti ṣàlàyé pé irọ́ àtí aṣinilọna ni ìròyìn pé wọn sì n lo òògùn ibà mẹ́jìlélógójì ti àjọ ile Yúrópù fagilé, fún ìtọ́jú. Àjọ náà ṣàlàyé pé èròjà Artesunate wa nínú àwọn òògùn ti wọ́n gbégi dínà wọ̀nyí, ó sì wá ní inú òògùn Arinate tí ó yàtọ́ gedegbe sí àwọn òògùn ibà ti a n lò ní orilẹ-ede Nàìjíríà.

A tún ṣe akitiyan làti ṣ’awari atẹjade lati ọdọ àjọ ilè Yúrópù, ti o kéde igbegi dina àwọn òògùn mẹ́jìlélógójì wọ̀nyí ṣugbọn a kò rí oun kankan yatọ sí ìròyìn ti a ti ri tele.

A tún ṣe àyẹ̀wò sí orí ààyè ayélujára àjọ ìlera àgbáyé WHO ni ibi ti a ti ri ìlànà lóri ìtọ́jú àìsàn ibà. Ilana náà ṣ’agbekalẹ àwọn òògùn ti wọn gbọdọ fi se ìtọ́jú àìsàn ibà, yálà fún aboyún, ọmọ wẹrẹ tabi obinrin ti o n to ọmọ lọwọ. 

Òògùn àìsàn ibà ti àjọ WHO fọwọsi ni òògùn artemether pẹlu lumefathrine, artesunate pẹlu amodiaquine, Artesunate pẹlu mefloquine, dihydroartemisinin pẹlu piperaquine ati artesunate pẹlu sulfadoxine–pyrimethamine. Awọn wọnyi ṣee lò fún àwọn ọmọ ọwọ, alaboyun ati eni tí ó ń fún ọmọ lọ́yàn.

“Awon ẹlòmíràn ń lo akopọ artemisinin pẹlu naphthoquinone lẹẹkan naa, lòdì sí ìlànà WHO, ti ó ṣàlàyé pé kí wọ́n lo artemisinin fún ọjọ mẹta. Kò sí ẹ̀rí tó dájú pé wọn lè lo akopọ yìí.”

“Iwadii fìdí rẹ múlẹ pe lílo òògùn Artesunate fún ìtọ́jú àìsàn ibà lè dènà ikú nínú àwọn ọmọdé àti agbalagba, yàtọ̀ sí oògún quinine (Ẹrí tí ó dájú wà).”

DUBAWA kan sí Jimoh Abubakar, agbẹnusọ ilé-isé ti o n rísí amojuto òògùn, oúnjẹ ati ohun mímu n’ilẹ wa, NAFDAC lati jẹrisi àwọn aheso wọnyi. Botilejepe ọgbẹni Abubakar ri iwe ifiranṣẹ wa, o sì ṣèlérí látí fún wa ni èsì, ṣugbọn a kò ri èsì kankan, titi di àsìkò àgbéjáde ìròyìn yii.

Kíni àwọn onimọ sọ?

Sunday Idoko, oniṣegun oyinbo ni Garki Hospital Abuja ṣ’àlàyé pé púpọ̀ nínú àwọn òògùn ti aheso naa gbe, ni won ko lo fún itọju ni orilẹ-ede Nàìjíríà. O ṣàlàyé pé akopọ  ti won le fi se itọju ni artemisinin ati lumefantrin, Artesunate ati amodiaquine, Artesunate ati mefloquine, Artesunate ati sulphadoxine-pyrimethamine.

“A ko lo ọpọlọpọ awọn oògùn wọnyi ni orilẹ-ede Nàìjíríà. Awọn oògùn ti a le fi se itoju àìsàn ibà ni artemisinin ati lumefantrin, Artesunate ati amodiaquine, Artesunate ati mefloquine, Artesunate ati sulphadoxine-pyrimethamine.”

Àkótán

Ìwádìí wà fihàn pé inú ìròyìn atijọ ni wón ti mu atẹjade akálékáko yìí. Kódà, ọpọlọpọ nínú àwọn òògùn ti wọn ka sílẹ̀, ni ko sí fún itọju ni orilẹ-ede Nàìjíríà. Awọn onimọ ṣàlàyé pé àwọn oògùn igbogunti iba ti a n lo ni orilẹ-ede yìí ba ilana àjọ WHO mu. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button