Fact CheckSecurityYoruba

Àwọn ohun t’o ní láti mọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà

Getting your Trinity Audio player ready...

Pípè fún ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà nííṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ààbò tó dojú rú tí onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ sì ń ṣẹlẹ̀, bíi ìjíjigbé-gbowó, ìṣekúpani, ìgbésùmòmí, olè jíjà àti àwọn irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà tilẹ̀ tojúsú púpọ̀ ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà. Bí àwọn ènìyàn kan ti ń sọ wípé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ni ìdáhùn sí ìṣòro wọ̀nyí, àwọn mìíràn gbàgbọ́ wípé ṣíṣe àtúntò orílè-èdè Nàìjíríà nìkan ni ó leè kápá ìṣòro ètò àbò. Àwọn kan tilẹ̀ ń sọ wípé orílè-èdè Nàìjíríà kò tíì dàgbà tó láti ní ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.

Ọ̀gá ọlọ́pàá ní orílè-èdè Nàìjíríà, olúbẹ̀wò àgbà, Kayode Egbetokun, tún ṣe àtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ kejìlélógún ọdún oṣù kẹrin ọdún 2024, nígbà tí ó wípé, orílè-èdè Nàìjíríà kò tíì dàgbà, kò sì tíì kátò láti ní ọlọ́pàá tí à ń darí ní ìpínlẹ̀. Ó fi kún ọ̀rọ̀ náà wípé, dípò dídá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ sílẹ, kí àwon àjọ tó ń rí sí ìgbòkègbodò ọkọ̀ lójú pópó (FRSC) àti àjọ àbò-araẹni-làbòìlú (NSCDC) ó parapọ̀ di ẹ̀ka kan lábẹ́ ilé-iṣé ọlọ́pàá àpapọ̀. Ó tún gba ìjọba níyànjú láti fi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n (30,000) kún àwọn ọlọ́pàá tuntun tí ìjọba ń gbà wọlé ní ọdọọdún láti leè tẹ̀’wọ̀n tí àjọ United Nations fi lélẹ̀.

Kíni ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ gaan?

Gẹ́gẹ́ bí a ti pèé, ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ jẹ́ ọlọ́pàá tí à dá sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ kan, tí ó ń ṣíṣe ìgb’ófinró ní ìpínlè náà, gẹ́gẹ́ bí a ti máa ń rí ní àwọn orílè-èdè alápapọ̀. Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ láti gbé àwọn òfin ìpínlẹ̀ ró àti láti fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ọlọ́pàá àpapọ̀ láti pèsè ààbò lórílẹ̀. Lára ojúṣe ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ni ṣíṣe iṣẹ́ ìwádìí ní ìpínlẹ̀ náà, ríran àwọn ọlọ́pàá agbègbè àbí ìgbèríko lọ́wọ́, gbígbé òfin ojú pópó ró, dídá àwọn ọlọ́pàá tuntun lẹ́kọ̀ọ́, àti àwọn ojúṣe mìíràn.

Ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ àbí ọlọ́pàá agbègbè kìí ṣe ohun tuntun. Ọ̀pọ̀ orílè-èdè ni ó ṣe àmúlò ọlọ́pàá ìpínlẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, orílè-èdè Argentina, Ositéríà, Brazil, Canada, Jẹ́mánì, India, Mexico, Spain, àti Orílẹ̀ Amẹ́ríkà, wà lára àwọn orílè-èdè tí wọ́n ti ní ọlọ́pàá ìpínlẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi àlàkalẹ̀ òfin ìpínlẹ̀, agbègbè àbí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan. Wọn a sì tún máa fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ọlọ́pàá àpapọ̀ pẹ̀lú.

Ǹjẹ́ orílè-èdè Nàìjíríà nílò ọlọ́pàá ìpínlẹ̀?

Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì pẹ̀lú olú ìlú (FCT) ni orílè-èdè Nàìjíríà ní. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀, iye ọlọ́pàá tí ó wà ní orílè-èdè Nàìjíríà fi díẹ̀ ju 370,000. Èyí kéré sí àlàkalẹ̀ àjọ United Nations tí ó gbàgbọ́ wípé, ó ní láti Jẹ́ ọlọ́pàá kan sí ènìyàn ọ̀táléníriwó ó dín mẹ́wàá (450)

A ní láti kọ́kọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kí á tó lè mọ̀ bóyá orílè-èdè Nàìjíríà nílò ọlọ́pàá ìpínlẹ̀. Ǹjẹ́ ètò àbò fi ẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ tó ní orílè-èdè Nàìjíríà? Ǹjẹ́ ipá ìjọba orílè-èdè Nàìjíríà leè ká dídá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ sílẹ̀ nípa owó níná? Ǹjẹ́ èyí kò leè ìdúnkokò mọ́ ni àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ kan tí a ti mọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀? Ó ha leè ṣeéṣe kí àwọn gómìnà àti àwọn tó di ipò òṣèlú mú ní ìpínlẹ̀, kí wọ́n ṣe àṣìlò àwọn ọlọ́pàá náà bí?  Bí a bá leè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀, ó ṣeéṣe kí á mọ̀ bí àsìkò ti tó fún orílè-èdè Nàìjíríà láti ní ọlọ́pàá ìpínlẹ̀. 

Kíni àwọn ohun tí ó leè tẹ̀yìn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ yọ?

Ó ṣe pàtàkì láti ṣírò àwọn ohun tí ó ṣeéṣe kí ó bá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ wá, torí pé, kò sí ohun tí ó ní ànfàní tí kò ní ṣùgbọ́n. Ó leè ṣeéṣe kí àwọn ànfàní pọ̀ ju ṣùgbọ́n lọ tàbí kí àwọn ṣùgbọ́n pọ̀ ju ànfàní lọ. Nígbà tí a bá gbé wọn lé orí ìwọ̀n, aóò le mọ irú ìpinnu tí aóò ṣe. 

Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù púpọ̀ àwọn ènìyàn, ó ṣeéṣe kí àwọn gómìnà àti àwọn tó di ipò òṣèlú mú ní ìpínlè, ṣe àṣìlò ọlọ́pàá ìpínlẹ̀,  bóyá láti fi dúkokò tàbí dẹ́rùba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò wọn. Fún àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ àṣìlò agbára ọlọ́pàá wáyé ní ìlú Èkó ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹrin ọdún 2024, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó gbìyànjú láti ri wípé ìpàdé àwọn ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn èrè ìdárayá igun ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos SWAN), kò wáyé. 

Yàtọ̀ sí èyí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fífi ipá mú àwọn ọ̀dó aláìṣẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, fífi ẹ̀sùn ọ̀ràn dídá lórí ayélujára kan àwọn ọ̀dọ́ àti fífi ipá gba owó lọ́wọ́ wọn, tún leè pọ̀ síi nígbà tí a bá dá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ ló wà láti fi ìdí èyí múlẹ̀. Ní oṣù kejìlá ọdún 2023, àwọn olùgbé ìlú Ebonyin ké gbàjarè fún ìrànlọ́wọ́ láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n ń dààmú wọn. Àkójọ àwọn ìwà ọlọ́pàá wọ̀nyí ló jẹ́ kí ìf’ẹ̀hónúhàn ti “EndSARS” wáyé.

Àwọn ohun t'o ní láti mọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà
Àwọn ọ̀dọ́ tó ń f’ẹ̀hónú hàn. Orísun Àwòrán: Foreign Policy.

Ohun mìíràn, bí ànfààní tó lè wáyé nípa dídá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ sílẹ̀ ni iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́. Láti leè ri wípé ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà fi ìdí múlẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ ní láti gba àwọn òṣìṣẹ́ tí yíò máa rí sí gbígbé òfin ìpínlẹ̀ ró. Nípa èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀, ló ṣeéṣe kí ìjọba ó gbà ṣí’ṣẹ́ ọlọ́pàá.

Ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, dídá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ sílẹ̀ yíò jásí níní ètò àbò tó mọ́yánlórí ju tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀nà wo ni èyí yíò fi rí bẹ́ẹ̀? Nígbà tí ìjọba yíò bá gba àwọn òṣìṣẹ́ fún ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, ó di dandan láti gba àwọn ọmọ ìlú tí ó sì mọ́ ojú ilẹ̀ àti gbogbo kọ̀rọ̀ àárín ìlú. Ìfarapamọ́ àwọn amòòkùnṣèkà yíò dópin nítorí, gbogbo kọ̀rọ̀ ìlú ni àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ yíò ti fín àwọn ọ̀daràn náà jáde bí ewú. 

Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ leè jásí sísúnmọ́ àtúntò orílè-èdè Nàìjíríà. Ọ̀kan nínú ohun tí àtúntò orílè-èdè yíò mú wá náà ni ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ nígbà tí agbègbè kọ̀ọ̀kan bá dá dúró tán. Pẹ̀lú àtúntò orílè-èdè Nàìjíríà, ìdàgbàsókè orílè-èdè tún leè yá síi.  Ọ̀kọ̀ọ̀kan làá yọ’sẹ̀ lẹ́kù.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »