Getting your Trinity Audio player ready...
|
Ahesọ: Fọ́nrán kan tí àwọn èèyàn pin káàkiri èrò alatagba ṣ’àfihàn arákùnrin kan to n ṣe àríyànjiyàn pelu arabinrin kan ni ilu London. Àwọn olumulo ikanni abẹyẹfo gbé ahesọ pé gómìnà ìpínlè Ondó, Arákùnrin Lucky Aitedayiwa ni ọkùnrin inu fónrán naa.
Abajade ìwádìí: Irọ ni. Biotilẹjẹpe okunrin ti a ri nínù fónrán naa fi ojú jọ gómìnà ìpínlè Ondo, kìíse arákùnrin Aitedayiwa.
Ìròyìn lẹkunrẹrẹ
Nínu iṣẹ oselu ayé òde òni, irọ́ àti asinilọna ni àwọn olóṣèlú ńlò láti fi ba àwọn akẹgbẹ wọn lórúkọ jẹ́. Wọn a ma lo ìròyìn ofege láti mu kí àwón eniyan ṣ’alaigbagbọ àwọn oludije, pàápàá ni asiko idibo.
Ní ìgbà miran, ojúsàájú tàbí arotẹ̀lẹ máà n mu ki awon ìròyìn èké wọ̀nyí mu’lẹ dáadáa, ti o si le fa ijakule fun oludije ni àsìkò ìbò.
Gomina ipinlẹ Òndó, arákùnrin Lucky Aiyedatiwa je òkan lára àwọn oludije fún ipò gómìnà ninu ìdìbòyàn ti yóò wáyé ni ọjọ́ kerindinlogun oṣù kọkànlá ọdun yii.
Arákùnrin Aiyedatiwa tí ó jẹ́ ọmọ ègbé òsèlú APC fé dije du ipò fómìnà fún odindin saa kan. Àwọn oludije míràn ni arákùnrin Agboola Àjàyí, eni ti o jẹ igbákejì gómìnà ni ìgbà kan rí àti àwọn oludije mẹẹdogun míràn.
Fónrán kan ni o gbòde kan laipẹ yii ṣafihan ọkunrin kan tí o n takuroso pẹlú arábìnrin kan ni ìlú London. Akọsori fónrán náà ni wípé gómìnà ipinlẹ Òndó lo wa nínú fónrán ọ̀ún.
“Ẹwo Gómìnà Òndó ni ìlú London. Ẹgba mi o. Eyi ni awon alaibikita eniyan ti wọn dije du ipò pàtàkì ni orileede wa. Iwa ibaje ree ni owo odindin gomina ìpínlè kan.”
Ninu fónrán náà, arákùnrin kan ti o wo fila dudu, igo oju, pelu aso dudu kan ni o n ba arábìnrin kan ja. Ninu itakuroso won, arabinrin kan naa sọ wípé okùnrin yii ti gba oun leti leemeji.
Àwọn eniyan to wa nitosi gbìyànjú láti pin wọn niya bi arabinrin náà ti n lọ aṣọ mọ́ọ lọ́rùn.
Olumulo ikanni abeyefo, ChinasaNworu (@ChinasaNworu) ṣe àtúnpín fónrán náà pèlu aheso pé gomina ìpínlè Òndó lo wa nínú fidio òún.
Eniyan kàn dahun pé, “Eyin ma tete ṣewọn. Ti o ba fi ojú ba ilẹ ejo pẹlú irọ́ yii, ṣe o mọ pé ọgbà ẹwọn niyen. Deji Adeyanju ma gbà e sílè.”
Olumulo míràn Justicenfairness (@JustICE_Fairn) so wipe, “Oun ti o ma mu ki wọn dibo fúun nìyẹn. O ma san owo riba fún ajọ INEC, awon olopa, ati adajo, loba dì gomina. Àwọn èèyàn ipinle Ondó o ni imo. Gomina máà sàn riba fun àwọn oníròyìn.”
Ahesọ náà tanka orí ero alatagba bi a ti ri ni àwọn ibi wònyí, eyi ati eyi.
Nitori ìtànkálẹ̀ fónrán yii, ati àwọn oun tí àwọn ènìyàn sọ nípa rè, DUBAWA ṣe ìwádìí lórí fónrán náà.
Ifidiododomule
DUBAWA wo fónrán náà, a sì ríi wípé, ènìyàn ọtọọtọ ni arákùnrin ti o wa nínú fidio yii ati gomina ìpínlè Ondó. Latari akitiyan arakùnrin náà ki o já ajabo lówó obìnrin ti o n lo asọ mọ lọrun, fila arákùnrin yii jabọ, oju re si han kedere. A ríi wípé, onítọ̀hún ni eji láàrin eyin rẹ̀, gomina Aiyedatiwa kò ní eji.
Irú imú ti arákùnrin inú fónrán náà ni yatọ sí ti arákùnrin Aiyedatiwa.
Koda, arákùnrin Allen Sowore, ẹni ti o jẹ oludamọran lórí irọyin sì Gomina Aiyedatiwa, fi idi re mu’lẹ pé, kìíse gómìnà ìpínlè Òndó lo wa nínú fónrán akalekako naa.
Arákùnrin Sowore rọ awon ènìyàn pe kí wọn wò fónrán náà daada, ki wọn sì wo iyatọ to wa nínú irisi arákùnrin naa ati ti gomìnà. O bu enu ate lu àwón eniyan ti won gbè ìròyìn eke káàkiri, o ni wọn jé olubanilorukọjẹ.
“A rọ àwọn ènìyàn pe kí wọn ṣe ayẹwo fónrán náà daada ki wọn le ri ìyàtọ̀ to wa l’ara arákùnrin inu fónrán yii ati gómìnà Aiyedatiwa,” Sowore lo sọ bẹẹ.
Bákan naa, agbẹnusọ gómìnà nipa ìròyìn, arákùnrin Sunday Abire sọ pé gomina Aiyedatiwa o tii kúrò ni orileede Nàìjíríà láti oṣù kejila ọdún 2023. O fi’kun wipe arákùnrin inu fónrán náà yàtọ gedegbe sí gomina ìpínlè Òndó. O ni ìyàtọ̀ wa nínú irisi won, irungbọn ati ihuwasi àwọn méjèèjì.
“Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa o tii fi orilẹ-ede Nàìjíríà silẹ lari ìgbà ti o ti jẹ gomina ni oṣù kejila ọdún 2023. Kìí síi ṣe ibeji. Aiyedatiwa dá wa láti òrun ki o le jẹ ìbùkún fun àwọn eniyan Obe-Nla ni ibile Ilaje ti ipinle Ondo, Nàìjíríà ati awon orílè-èdè agbaye.
“Ti a bá wo fónrán náà fínífíní, a ríi wípé irùngbòn ọkunrin yii yàtò sí ti gomina wa, koda ko sọrọ bíi Aiyedatiwa.”
Ko sí ojulowo ìwé iroyin to ṣe atilẹyin fónrán náà, koda ko sí ẹnikẹni ti o le ṣe ifimule pé gomina náà lo wa nínú fónrán ọ̀ún.
Akotan
Ìwádìí DUBAWA fihàn pe arákùnrin inu fónrán yii fi ojú jọ gomina Aiyedatiwa sùgbòn eniyan otooto ni wọn. Ijoba ìpínlè Ondó náà ti bú ẹnu ate lu àwón to n ṣ’atunpin fónrán, o tokasi pé àwòn ti wọn fe ba gomina lórúko je ṣaaju ibo, ni won gbè fidio náà jáde.