YorubaElectionsMedia Literacy

#Idibo Ipinle Ondo: Awọn Oludije fún ipò gomina niwonyii

Getting your Trinity Audio player ready...

Àjọ to n risi eto idibo orilẹ-ede Nàìjíríà so laipẹ yii pé àwọn oludije metadilogun ni won du ipò gomina ipinle Ondo. Eto idibo náà yóò wáyé ni ojo kerindinlogun osu kọkànlá ọdun yìí. 

Eyi ni àròkọ isọniṣoki lórí àwọn oludije metadilogun ọ̀ún pẹlu àlàyé lórí ẹgbẹ òsèlú tí wọn wá. 

Falaiye Ajibola (A)

Falaiye Ajibola jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord. Ìlérí rẹ fun àwon ará ìlú ni wipe oun a gbajumọ awọn ọrọ tó ṣe pàtàkì, pàápàá nipa òrò ajé ati bi ara ṣe ma tuu oníkálukú.

Ile eko gíga Yunifasiti Ekiti ni ọ ti kẹkọọ gbọye. Odu ni arakunrin Ajibola je, kiise aimo f’oloko nínú oro òsèlú, o bere isẹ oselu pelu oselu agbegbe. Arakunrin naa jẹ ọmọ ọdún eerinlelogota, Samuel lkuyajolu sì gbé igbákejì rẹ̀.

Akinuli Omolere (AA)

Akinuli Omolere ni oludije egbe òsèlú Action Alliance ninu idibo náà, leyin ti o gbégbá orókè ninu ibo abele. Arakunrin naa jẹ alakoso agba ile-ise Lery Hago ti o máa n risi ọrọ nípa ìrìn-àjò. Koda, o ti ṣ’èdá silẹ ọpọlọpọ ile-ise pelu awon onísòwò egbe re. Adeyemi Oluwatoyin ni igbákejì.

Ajayi Adekunle  (AAC)

Akewi ni Ajayi Adekunle, a-ja-fun-eto-omoniyan, òṣèré tiata, àti soro-soro. Arakunrin Àjàyí ti dá sí ọrọ nípa ifehonuhan lórí awọn ilana ijoba to le pa ará ìlú lara. Koda, o ti se asoju awon egbé ti won tako iwa ibaje awon oloselu. 

Bi o ti jẹ oludije egbe AAC, èyí ṣàfihàn ìkópa re ninu oselu orile-ede. Dada David ni amugba legbe. 

Nejo Adeyemi (ADC)

Agbẹjọro ni Nejo Adeyemi, oun si ni oludije fún ipò gomina ni ègbé òsèlú African Democratic Congress. Oludije naa jẹ ọmọ ọba ilu Mahin ni ijoba ibile Ilaje ti ipinle Ondo, àti òkan lára awon Olu ilẹ iṣẹ Myson Law Practice.

Arakunrin Adéyemí di oludije ADC leyin ti o gbégbá orókè ninu idibo abele ti egbé òṣèlú naa ṣe ni ojo kerindinlogbon osu kerin odun 2024. Ìlérí rẹ fun àwon ará ìlú ni pe oun a dari ijoba dáadáa, oun a fi idi ofin múlẹ, ètò ẹkọ a ri iyipada, koda eto ilera ni ìpínlè naa a yipada si otun. Ibrahim Olaide ni amugba legbe re ninu idibo to n bọ.

Akinnodi Ayodeji (ADP)

Akinnodi Ayodeji ti gbogbo eniyan mo ṣì Ẹjańlá, jẹ onísòwò nla àti oniselu. Won bíi ni ojo kesan osun kaarun odun 1985 ni ìlú Ondo. Arakunrin Ayodeji wa lati idile onígbàgbọ. Ile eko alakobere St. Mary’s Nursery & Primary School lo ti bèrè síí kawe, bakan naa o lo ilé èkó gírámà Ondo High School. Leyin èyi, o lo Yunifasiti ìlú Benin ti o ti kẹkọọ gbọye ninu imo kọmputa.

O tẹsiwaju lọ ilé ẹkọ Metropolitan School of Business and Management ni ìlú oba, bakan naa ló kẹkọọ yege ni London Real Estate Academy. Moyosola Olorunmonu ni amugba legbe e.

Lucky Ayedatiwa (APC)

Odun 1975 ni wón bí Lucky Aiyedatiwa, eni ti o jẹ gomina ipinle Ondo. Leyin ọdun diẹ, o gba ìwé erí mokekoyege láti Kọlẹẹjì eko. Leyin èyi, arákùnrin Aiyedatiwa lọ Yunifasiti Ibadan ni ibi ti o ti pari eko ninu imo amojuto òwò síse ní odún 2001.

O morile Lagos Business School – Pan Atlantic University, ni ibi ti o ti gbà ìwé erí mokaweyege ninu imo ìṣàkóso ìṣòwò ní odún 2009. 

Ní odún 2013, Aiyedatiwa kẹkọọ gbọye ni Yunifásítì ìlú Liverpool. Laarin odun 2018 si 2019, arakunrin Aiyedatiwa se asoju ipinle Ondo ninu igbimo to risi idagbasoke agbegbe Niger Delta. Ní odún 2020, won yan arakunrin Aiyedatiwa gegebi igbakeji gomina Rotimi Akeredolu to jade laye ni oṣù kejìlá odun 2023. Leyin èyi, Aiyedatiwa bọ si ipò gomina. 

Olatunji Popoola (APGA)

Ọmọ ọdún merindinlaadorin, o si jé oludije egbé APGA. Igbákejì re ni Taiwo Adedeji, omo ogoji odun ti o jẹ oludari egbé All Progressive Grand Alliance (APGA) ni ìpínlè Osun. Ní odún 2023, awon ọmọ ẹgbẹ akojọpọ egbé oṣelu ni ìpínlè Òsun dibo o ṣee f’ọkan tan fún arakunrin Popoola gegebi oludari IPAC, èyi to se ijẹrisi ipa to ti ko ni àárin awon egbé òṣèlú.

Ní odún 2024, arakunrin Popoola ni oludije fún gomina ipinle Ondo labẹ àsìá egbé APGA.

Olorunfemi Ayodele (LP)

Olorunfemi Ayodele jẹ oludije egbé òṣèlú Labour Party. O jẹ akọwe teleri ẹkùn kan labẹ egbé oṣiṣẹ TUC. 

Arakunrin naa, ọmọ ọdún okandilogota jẹ ọmọ bíbí Uro Ajowa, o kawe ni orilẹ-ede Amẹrika, Olabisi Adu si ni igbákejì re.

Olugbenga Edema (NNPP)

Olugbenga Edema jẹ ọmọ ìlú Ogogoro, ti ibilẹ Ilaje ni ìpínlè Ondó. O jẹ oloselu, agbẹjọro, àti olùrànnilọ́wọ́. Laipe yii ni arakunrin Edema kuro legbe APC si NNPP. O jẹ oloselu kan to gbagbo pe ijoko ijoba gbodo kaari ẹkùn métèèta to wa ni ìpínlè Ondó. 

Agboola Ajayi (PDP)

Agboola Ajayi jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party. O wa lati ilu Kiribo ni ijoba ibile Ese Odo. Ile èkó gírámà ilu Kiribo lo ti kawe. Leyin èyi, o morile Methodist High School ni ibile Okitipupa. O lo taara Si Yunifásítì Igbinedion ti ipinle Edo ni ibi ti o ti kẹkọọ gbọye ninu Ise agbẹjọro.

Egbé òṣèlú Social Democratic Party ni arakunrin Àjàyí ti bere isẹ oselu ti o si jé oludari egbé naa ní odún 1988. Koda, o se asoju ẹkùn Ilaje/Ese Odo ni ilé igbimọ asojusofin.

Francis Alli (PRP) 

Francis Alli ni oludije àti akowe egbé òṣèlú Peoples Redemption Party. O wa lati ijoba ibile Okitipupa. O kẹkọọ gbọye ninu imo ìṣàkóso àwùjọ lati Yunifasiti ìlú Èkó. Imo eko nípa iṣẹ àti ihuwasi awon ènìyàn yóò ràn lọwọ, gegebi gomina, lati dojuko ipenija ti awon èèyàn ni ìpínlè naa bá n lakoja.

Akingboye Bamidele (SDP)

Wón bí Akingboye Bamidele ni ìlú Igodan-Lisa, ni ibile Okitipupa. O kẹkọọ gbọye ninu imo ìṣàkóso òwò síse ní kọlẹẹjì Lagos Business School, Pan-Atlantic University, ati Herriot Watt University, Edinburgh, ti ìlú oba. 

Ogoji odun gbako ni ogbeni Bamidele ti fi se ìsàkóso òwò síse. Gegebi Olùdarí ile-ise Benshore Maritime Services, arakunrin naa ti kopa ninu awon ìlànà ti a gbé kalẹ lori iṣẹ ori omi. 

Otitoloju Akinmurele (YPP)

Oludije egbé òṣèlú YPP. Ninu oro re, o ni oun a dojú ìjà ko awon ipenija ni ipinle naa, pàápàá awon eyi to wa latara iwa ibaje àti aibikita. 

Akinmurele máa n saba soro lórí ìdí ti iyipada se gbodo dé ba ipinle Ondo, pàápàá pẹlú ohun amulo ti adeeda ti fi ta ipinle naa lóore. 

Adegoke Kehinde (YP)

Adegoke Kehinde jẹ onimo nípa òfin, òṣèlú àti ìdàgbàsókè awon ọdọ. O karamasiki oro awon odo, ẹkọ won àti ìṣe. 

Abbas Mimiko (ZLP)

Abbas Mimiko jẹ Oludije Labe àsìá egbé òṣèlú Zenith Labour Party. O jẹ àbúrò gomina teleri, Olusegun Mimiko. Sugbon, Oludije naa ti salaye pe òun a dije du ipò gomina nipasẹ iṣẹ ọwọ oun.

O jẹ dokita ti máa n se itoju ọkan ati ọpọlọ. O kẹkọọ ise oogun oyinbo ni Yunifasiti Eko. Arakunrin Mimiko ti mẹnuba ọrọ aje, iṣẹ ọgbin, atunse ẹtọ ẹkọ àti eto aabo ni ìpínlè Ondó. 

Awon Olujide yòókù 

Ko sí alaye to daniloju lórí àwọn Oludije meji: Ogunfeyimi Kolawole ti egbé òṣèlú Allied Peoples Management ati Fadoju Babatunde, ọmọ ẹgbẹ òṣèlú Action Peoples Party. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »