Fact CheckHealthYoruba

Irọ́ ni! Àgbálùmọ̀ kò le wo akọ jẹ̀díjẹ̀dí, àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhèsọ: Fọ́nrán kan láti ọwọ́ arashadyworldwide lójú òpó TIk Tok tí àwọn èèyàn tí wọ́n lé ní 77 thousand ti wò, tí wọ́n tún fi ṣọ wọ́ ló jú òpó WhatsApp, pé àgbálùmọ̀ àti kóóró rẹ̀ le wo akọ  jẹ̀díjẹ̀dí àti àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru.

Irọ́ ni! Àgbálùmọ̀ kò le wo akọ jẹ̀díjẹ̀dí, àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru

Àbájáde: Ọ̀rọ̀ láti ọwọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó fihán pé, kò sí àrídájú pé àgbálùmọ̀ tàbí kóóró rẹ̀ le wo akọ jẹ̀díjẹ̀dí àti àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru. Ófégé ni ọ̀rọ̀ náà.

Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Fọ́nrán kan tó lé de ló jú  òpó TIkTok láti ọwọ́ ẹnìkan tórúkọ rẹ́ jẹ́ arashadyworldwide, tó tún lé de lójú òpó WhatsApp ṣàlàyé pé àgbálùmọ̀ àti kóóró rẹ̀ le wo akọ jẹ̀díjẹ̀dí àti àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru. 

Gẹ́gẹ́ bí fọ́nrán ọ̀hún ṣẹ  wí, ẹnikẹ́ni tó bá ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru ni kó sa ọ̀pọ̀lọpọ̀ kóóró àgbálùmọ̀, kó sì mú kóóró funfun inú rẹ̀, kó sá, kó gbẹ, kó’gun lúbúlúbú, kí wón lo síbí ẹ̀kọ kan lójúmó, pé àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru ọ̀hún  yóó sàn.

Fọ́nrán ọ̀hún tèsìwájú pé akọ jẹ̀díjẹ̀dí ni yóó sàn tí wọ́n bá lo síbi ẹ̀kọ kan tinú kóóró àgbálùmọ̀ ọ̀hún, pẹ̀lú ọṣàn wẹ́wẹ́.

Àgbálùmọ̀ jẹ́ èṣo tó gbajúgbajà nílẹ̀ Yorùbá láti oṣù kíní di oṣù kerin.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfààní ni àgbálùmọ̀ ṣe ní àgó ara ọmọ èèyàn, ó jẹ́ pàtàkì oríṣun Vitamin C, ó ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́bí irinsẹ́ tó ń fọ ìdọ̀tí ara, ó ń ran óúnjẹ lọ́wọ́ láti dà àti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní fún àgó ara.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pèlú DUBAWA, Adarí ìpòlongo fún ọ̀rọ̀ ìlẹ̀ẹ̀ra ìjọ̀ba ìbílẹ̀ ìwọ̀oorùn Ilésà,  ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tó tún jẹ́ òṣìṣẹ́ nọ́ọ́ṣì, Tolúlọpẹ́ Ọlájùmòkẹ́ ṣàlàyé pé àgbálùmọ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní  fún àgó ara bí ìrànwọ́ láti jẹ́ kí óúnjẹ dà níkùn àmọ́ kò sí àrìdájú pé ó le wo àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí akọ jẹ̀díjẹ̀dí sàn.

Ó tèsìwájú pé “àgbálùmọ̀ ṣe àgọ́ ara ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní bí àwọn èṣo tó kù àmọ́ kò sí ìwádìí kankan tó fì dí rẹ̀ mú lẹ̀ pé òhun àti kóóró rẹ̀ le wo àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí akọ jẹ̀díjẹ̀dí”. 

DUBAWA tún kàn sí Dókìtà Adéolú Olúsódo, adarí ilé ìwòsàn Atáyẹ́sẹ Òdógbolú, Ìpínlẹ̀ Ògùn lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ṣàlàyé pé kò sí àrìdájú pé àgbálùmọ̀ tàbí kóóró inú rẹ̀ le wo àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí akọ jẹ̀díjẹ̀dí. 

Arákùnrin Olúsódo wí pé “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní ló wà nínú jí jẹ àgbálùmọ̀ fún àgó ara èèyàn àmọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó kò tí rí àrìdájú pé ó le wo akọ  jẹ̀díjẹ̀dí tàbí àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru”. 

A tún kàn sí Arákùnrin Gbẹ́nga Àbàtà òṣìṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí nílé Ẹ̀kọ́ Gbogbonìse ìjọba àpapọ̀ tìlú Ẹdẹ, ẹ̀ka Nutrition and   Dietetic ṣàlàyé pé àgbálùmọ̀ kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ fibre tó le dènà jẹ̀dìjẹ̀dí àmọ́ ìwádìí kò fìdí rẹ̀ múlè pé ó le wo àrùn jẹ̀díjẹ̀dí. 

Ó tèsìwájú pé “àgbálùmọ̀ ló tún ní sodium kékeré àmọ́ kò sí àrìdájú pé ó le wo akọ jẹ̀díjẹ̀dí tàbí àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru”. 

Àkótán

Àhèsọ pé àgbálùmọ̀ tàbí kóóró rẹ̀ le wo akọ jẹ̀díjẹ̀dí àti àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru jẹ́ ófégé tó le si àwọn èèyàn lọ́nà.

The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to facilitate the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »