Ahesọ: Àtẹ̀jáde akalekako kan ló gbé aheso pé bánkì àpapọ̀ orílè-èdè Nàìjíríà (CBN) pàṣẹ kí wọ́n ti Opay, Kuda ati Palmpay pa.
Abajade iwadii: Irọ́ ni. Ìwádìí wa fihàn pé kò sí atẹjade kankan láti ọdọ CBN tàbí ojúlówó iroyin nípa ọrọ náà. A ṣakiyesi wípé olumulo ìkànnì abéyefò Twitter tó gbé ìròyìn ofege náà ti paarẹ kúrò lójú òpó rẹ̀.
Iroyin lẹkunrẹrẹ
Ninu gbogbo rògbòdìyàn náírà tuntun tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kojú lọwọ, olumulo ìkànnì abéyefò kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ Olamide (@DymanFocus) gbé ahesọ pé gómìnà bánkì àpapọ̀ orílè-èdè Nàìjíríà, Godwin Emefiele tí palaṣẹ pé ki wọn ti àwọn bánkì wọ̀nyí pa: Opay, Kuda ati Palmpay, bẹrẹ láti ọjọ kerindinlogun, oṣù keji, ọdún 2023.
Ọ̀rọ̀ yii dá ìjayà sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọn kò sì farabalẹ láti mọ boya otito wa nínú ọrọ naa. Awọn eniyan bèrè síni gbé owó wọn kúrò ni àwọn ilé ifowopamọ wònyí sì òmíràn. Won si tún satunpin ìròyìn èké yi si awọn ọ̀rẹ́ àti mọlẹbi wọn lórí ìkànnì ibaraẹnisọrọ WhatsApp ati ìkànnì ibaraenidore Facebook. Wọn rọ àwọn mọlẹbi àti ọrẹ wọn ki awọn naa gbe owó wọn kúrò ni awọn ilé ifowopamọ ti a darukọ wọnyi.
Akiyesi wà ní wipe ahesọ yii tànká, pẹlupẹlu gbogbo oun ti ó n sele nipasẹ owó náírà tuntun yìí lo je ki a se itopinpin ọrọ naa láti mọ boya ooto ni tabi irọ́. Nítorí, irú atẹjade èké yìí lè dá rudurudu sílẹ̀ láwùjọ pàápàá fún àwọn tí wọn ní owo sí awọn banki wọnyi.
Isaridaju
Ní ìgbà tí a ṣe ibewo sí ojú òpó olumulo ìkànnì abeyefo naa @dymanfocus, a ríi wípé nínú atejade miran, o ṣalaye pe orisun ìròyìn oun ni, “igbo ti ojo ti lo lori re ati tábà líle”. Eyi je aami àpẹẹrẹ pe irọ́ ni atejade akọkọ.
A ṣakiyesi pé atẹjade akọkọ ti parẹ kúrò lójú òpó @dymanfocus.
DUBAWA tún se ìbèwò sí ààyè ayélujára bánkì apapo orile-ede wa, kò sì sí oun tó jọ bẹẹ. A tún ṣamulo kókó ọrọ lati se iwadii wa, a ríi wípé kò sí ojúlówó ile-ise ìròyìn tó gbé ìròyìn naa. Lórí ìkànnì Instagram, a ríi wípé ọkan nínú àwọn ilé ifowopamọ náà, Opay @opay.ng ti takò ìròyìn náà.
“A ti pe àkíyèsí wa sí atẹjade akalekako kan ti won satunpin káàkiri ori ayelujara nipa banki wa Opay. Atẹjade náà daba pé bánkì apapo CBN fe ti ile-ise wa pa. Irọ́ àti asinilona ni iroyin yii,” Opay lo sọ èyí.
Ilé ifowopamọ Palmpay náà takò iroyin yii latari ojú òpó wọn lórí ikanni abeyefo Twitter. Wọn fi awọn ọmọ orilẹ-ede Nàìjíría lọkàn balẹ pé kò sí ìyọnu kankan, ati wipe awọn ṣi wà lẹnu iṣẹ, won sì ṣeé gbẹkẹle.
Akotan
Ìwádìí wa fihàn pé ìròyìn èké ní ọrọ náà. A kò ri àtẹ̀jáde tàbí ojúlówó ìròyìn tó ṣatileyin ahesọ náà. Àti wípé olumulo ìkànnì abéyefò Twitter tó fi ọrọ yii sita ti mú kúrò lórí ojú òpó rẹ̀.