Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Olumulo ikanni X, @Fact sọ wípé eniyan ti kò ba rẹ’jú tàbí sun oorun botiye, onitoun le fori lugbadi ikú àìt’ọ́jọ́.

Abajade iwadii: Òdodo ọ̀rọ̀. Ojulowo iwadii ti àwọn onímọ̀ sayẹnsi gbe jade fihan pe lootọ, ti eniyan kò ba fi oju kan oorun tabi sun bótiyẹ, ẹni naa wa ninu ewu ikú òjijì.
Ẹkunrẹrẹ alaye
Oorun ṣe pataki si ìlera ara eniyan, nítorí ipa ti o lè kó ni ìlera ọpọlọ, ipò ọkàn, òye, ati ihuwasi. Gẹ́gẹ́bí ounje ati eré idaraya ti ṣe pataki si ìlera eniyan bẹ́ẹ̀ naa ni ki eeyan rẹ’jú lasiko to to ati iye igba to ye le se anfaani fun awon omoonu kookan, ro eya oki ara l’agbara, mu idagbasoke wa, a tun se iranwo fun opolo, kódà ijamba a dinku fun eniyan bee.
Agbalagba nilo lati sun fun wakati meje si mesan. Eni ti ko ba rẹ’jú daadaa wa ni ewu àìsàn gbẹmi gbẹmi, o si le mu irewesi dani.
Ni ojo keta osu keje, odun 2025, olumulo X kan @Fact sọ pe eni ti ko ba sun daadaa wa ninu ewu ikú àìt’ọ́jọ́. Oun ti o ko si oju opo re, “Ki eeyan ma sun fun daadaa le fa ikú àìt’ọ́jọ́.”
A ṣe akiyesi pe awon olumulo miran fesi si ọrọ naa, àwọn kan gbagbọ, bẹ́ẹ̀ lawọn kan ò gbagbọ.
Olumulo ikanni X, Ella Moore (@monagan1979) so pe, “Eyi ṣ’ẹru ba’ni pupọ! Je ki n lọ tete wa nkan se si bi mo se n sun si ni kiakia. Aṣamulo kan @Joshuastock32 maa n tenumo pataki oorun fun eniyan— je ki n lo ṣ’ewadii oun to ni lati sọ.”
Elomiran No 1 CHELSEA FC HATER (@reverend_eskay), ṣ’awada pe “Nje eyi tunmọ si pe mo ma ku l’ewe? O ti pe ti mo ti mo.”
Ṣugbọn aṣamulo kan, Omo Daada (@Beamborkate1) tàka e danu, o ni, “Olorun o ni jẹ ki n ri ikú òjijì.”
Iwasneveronearth (@_smallwig) fesi pe, “Ǹjẹ́ o ni oun to le fi satileyin aheso yii?”
Lootọ, imọ sayẹnsi fi idi rẹ̀ mu’lẹ̀ pe oorun ṣe pataki fun ìlera ara, ṣugbọn àwọn eeyan o gbagbo ahesọ pe àìrórunsùn le fa ikú òjijì. Àwọn èsì si aheso naa lo mu ki DUBAWA gbe iwadii yi jade.
Ifidiododomule
Atejade kan lori Sleep fi’han pe agbalagba ti kò sùn to wakati mẹ́fà ni òru le lugbadi ikú àìt’ọ́jọ́, iwadii fihan pe àwọn eeyan ti won kin sùn daadaa le saaju elomiran ku. Àwọn ti won ni idojukọ aiororunsun ni gbogbo igba le ni opolopo idojuko bii wahala omoonu, igbinikun, ati beebeelo, àwọn nkan wonyi si le fa aarun ọkàn ati itọ ṣuga.
Atejade miran ninu Journal of the American College of Cardiology fi idi rẹ̀ mú’lẹ̀ pe àwọn eniyan ti oorun wọ́n se segesege le tete fori lugbadi aisan ọkan tabi ikú òjijì. Awon oniwadii salaye pe ailesùn daadaa le mu ki nkan baje laago ara.
Won ni àìróorunsùn le fi eniyan sinu ewu aisan okan, nitori o le fa ẹjẹ riru. Awon nkan wonyi maa n fa aisan okan, aisan rọparọsẹ, ati ki okan ma sise boseye, àwọn yi wa lara oun to n fa ikú òjijì lagbaye. Eyi safihan ewu to gbeyin ailesùn daadaa.
Iwadii kan ti won gbe jade ni odun 2024 laarin egberun agbalagba ni orileede Naijiria fihan pe àwọn eeyan ò sùn daadaa. Olori àwọn oniwadii Jesujoba Olanrewaju kilọ pe àìrórunsùn laarin àwọn agbalagba wonyi le mu ki aisab okan, ito suga ati ikú àìt’ọ́jọ́ leke si ni orileede Naijiria.
Awon onimo soro
Adeyemi Adefidipe, eni ti o je dokita agba ni ile iwosan idanileko ti Yunifasiti Obafemi Awolowo ni Ile Ife, sọ pe iwadii fidirẹmulẹ pe, àìrórunsùn le fa ikú àìt’ọ́jọ́.
O fikun pe aisan ọkan wa lara àwọn nkan to n fa ikú àìt’ọ́jọ́ lagbaye, paapaa fun àwọn okunrin.
“Asopọ wa laarin àìrórunsùn ati ikú àìt’ọ́jọ́, nitori àìrórunsùn le fa ifunpa giga, eyi si le mu ki okan ma sise bótiyẹ.”
Fun àwọn ti ise po fun, Adeyemi gba won nimoran pe ki won gbiyanju lati wa asiko fun oorun. “Gbogbo eda alaye ye ko sùn fun wakati mefa ati jubeloo lojumo kan nitori o maa n ran ara lowo lati bọsipo ati lati di ọ̀tun. Koda, o dara ki eeyan fi erọ telefoonu re ati ero amohunmaworan si yara ibomii. Yago fun ounje apoju ki o to lo sùn, ki o si ko gbogbo wahala ise danu kuro ni okan re, eyi a gba o laaye lati sùn daadaa.”
DUBAWA ba Samson Babalola sọrọ, ẹni ti o jẹ oga ile-iṣẹ Wellness and Occupational Health ni Total Health Trust Limited, ati akowe “Resilient Work Lives.” Samson so fun wa pe àìrórunsùn le tete fa ikú òjijì.
“Àwọn eeyan ti wọn kò sùn to wakati meje ni ooru ojo kan le tete fori lugbadi ikú òjijì, bakan naa ni won le ni aisan okan, aisan rọparọsẹ, aarun jẹjẹrẹ ati ti ọpọlọ,” Samson lo sọ bee.
O gba imoran pe ki eeyan ma sùn deedee, ji lasiko, pa ina ti o ba fe sùn, ko ariwo danu, yago fun ọti to ni caffeine ninu ni’rọle, ki eeyan si gba òrùn si ara loorekore.
“Ti segesege oorun ba tesiwaju sii, leyin ti eeyan ti ṣe gbogbo nkan wonyi, yoju si dokita re. Oorun se pataki lago ara. Oun ni opo to di ìlera ọrọ ati emi gigun mu,” dokita naa lo sọ bee.
Akotan
Iwadii ati àwọn onimo fi mu’le pe àìrórunsùn ati ki eeyan ma sun segesege le fa ikú àìt’ọ́jọ́, nitori onitoun le ni aisan okan, aisan itọ ṣuga ati àwọn aarun miran.