Fact CheckHealth

Ǹjẹ́ èèpo ẹ̀yin igi kaṣú le è pa oró ejò?

Àhesọ: Èèpo igi kaṣú ma ń pa oró ejò. 

Ǹjẹ́ èèpo ẹ̀yin igi kaṣú le è pa oró ejò?

Àbájáde ìwádìí: Èyí jẹ́ ìṣinilọ́nà. Ìwádìí wa fihàn pé kò sí àbájáde sáyẹ́nsì kankan tó fí ìdí múlè wípé èèpo ẹ̀yìn igi kaṣú le è pa oró ejò.

Ìròyìn Ní Kíkún 

Ìgi kaṣú jẹ́ ohun ògbìn èyí tó gbajúmọ̀ káàkiri. Dípò wípé ó wọ́pọ̀ jù ní ìlú Brazil, igi yìí ti wá di ohun tí à ń gbìn ní ìlú Nàìjíríà, Vietnam, India, Indonesia, Philippines, Benin, Guinea-Bissau àti Ivory Coast.

Bí èsó rẹ̀ ṣe jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn dá mọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni èpo ẹ̀yìn igi rẹ nítorí àwọn ànfààní tó wà lára rẹ̀.

Fún àìmọye ọdún ni àwọn ènìyàn ti ń fi èpo igi kaṣú ṣe ìwòsàn orísirísi ààrùn bíi kòkòrò ará, iredodo, àti ìrora. Ó kún fún èròjà bíi “anacardic acid” tó ní agbára láti gbógun ja onírúurú kòkòrò àìlèfojúrí.

L’ẹ́nu àìpẹ yìí, àtẹ̀jíṣẹ́ kan tí ó ń káàkiri lórí ẹ̀rọ ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ “WhatsApp” wípé èpo ẹ̀yìn igi kaṣú yóò pa oró ejò pátápátá.

“Yóò pa gbogbo oró kóró láti ara ejò ohun, kódà bó bá jẹ́ Àgbádú,” díẹ̀ lára àtẹ̀jíṣẹ́ yìí kà báyìí.

Ǹjẹ́ èèpo ẹ̀yin igi kaṣú le è pa oró ejò?
Àhesọ tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀.

Lábẹ́ àtẹ̀jíṣẹ́ yìí ni wọ́n kọ ẹ̀bẹ̀ pàtàkì sí pé kí àwọn ènìyàn máa pín àlàyé yìí kiri.

Àhesọ yìí kìí ṣe títún. Ni ọdún 2022, Balarabe Yazid, Ibrahim Danjuma Bebeji, Imajijio Ufuamaka àti àwọn mìíràn pín káàkiri ẹrọ ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ “Facebook”.

Láfikún, ọ̀pọ̀ ìgbà la ti rí ibi tí àwọn ènìyàn ti gbàgbọ́ pé èpo ẹ̀yìn igi kaṣú le ṣe ìwòsàn oró ejò.

Fún àpẹrẹ, Haruna Abdullahi rí ọ̀rọ̀ náà bíi àlàyé tó wúlò.

Ó dá si wípé: “Alaye kíkún tó sì wúlò ni èyí. Kí ọlọ́run bùkún rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀.” 

Nínú àtẹ̀jíṣẹ́ mìíràn, Udu Ego dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó sọ ọ̀rọ̀ náà.

“Daalu Nneoma fún ẹ̀kọ́ yìí,” Arákùnrin Ego sọ ni èdè ígbò.

ìpòruru àhesọ yìí àti aburú tó lè fà ni ó fa ìwádìí yìí.

Ìwádìí

Igi kaṣú ti wà láti ọjọ́ pípẹ́. Orúkọ sáyẹ́nsì rẹ̀ la mọ̀ sí “Anarcadium Occidentale”. Èpo ẹ̀yìn rẹ̀ tó kún fún èròjà tánísì la fi ń ṣe ètò ìwòsàn ìbílẹ̀.

Yàtọ̀ sí èyí, “anacardic acid àti cardol” tó ń pà ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò àìlèfojúrí ló wà nínú èpo yìí.

Antivenom” ni oògùn tí à ń lò fi pa oró. Oríṣi rẹ̀ ló wà fún oríṣi oró. Ó sì léwu, tí a bá lo èyí tí kò tíì ní àrídájú fún ìwòsàn. Bí a bá lo èyí, ó le bá ẹ̀mi lọ.

Ìwádìí kan tí vásitì Mysore gbé jáde ní ìlú India, pẹlú ẹmọ́, fí àrídájú hàn pé oje tí a fà jáde lára èèpo ẹ̀yìn igi kaṣú ṣe ìdíwọ́ fún “muscle trauma,” ara wíwú, àti pipadanu ẹ̀jẹ̀ (bleeding) lójú ọgbẹ́ ejò. Ó tó ìgbà díẹ̀ kí ẹmọ́ yìí tó kú. Lẹyìn ìwádìí, àwọn olùwádìí yìí fìdí rẹ̀ múlẹ pé èèpo igi kaṣú da fún aájò àkọkọ (first-aid treatment) tí ejò ba ṣán ènìyàn. Ṣùgbọ́n, kò lè dánìkàn wo ẹni tí ejò ṣán sàn.

Gẹ́gẹ́ bí ìlànààjọ ètò ìlera àgbáyé (World Health Organization) fi kalẹ̀ lórí ìtọjú ìjàmbá ejò, “púpọ̀ nínú ọ̀nà ìbílè tí à ń gbà ṣe ìtọ́jú ọgbẹ́ ejò ló léwu.” Nítorí náà, àjọ WHO ò faramọ́ lílo àgbo fún ìtọjú ara.

Èrò Amòye

Amoye nípa ẹranko (zoologist), Eric Kuju ṣe àlàyé fún DUBAWA pé lótìítọ́ ni èèpo igi kaṣú ní àwọn èròjà tó lè ṣe ìwòsàn. Sùgbọ́n, kò sí àbájáde kánkan nípa lílo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi anti-vẹ́nọ́mù.

Nípa ti ìwádìí tí ẹ̀ka Biochemistry Department ti vásitì Mysore ṣe, ẹ̀mọ́ ni wọ́n lò. Wọn kò ṣe àgbéyẹ̀wò yìí lára eranko n’lá  bíi ọ̀bọ tàbí ènìyàn. 

Láfikún, o wípé: Pé o ṣiṣẹ́ jù ní kò ní jẹ́ kí oró ejò náà yára lọ jìnà. Oje èpo igi kaṣú, kò lè gba èmi ẹni tí ejò bá ṣán là.

Bákanáà, Rachel Vincent, amòye nípa ògùn (pharmacist) wí fún DUBAWA pé kò sí ohun tó ń jẹ́ pé à ń lo igi kaṣú fí ṣe ìtọ́jú oró ejò. “N kò gbọ rí,” ni arábìnrin yìí sọ.

Kódà, a tún ri pé, Africa Check, The Healthy Indian Project, àti AFP fact-check ti dìbọ́ǹkì àheso yìí tẹ́lẹ̀ rìí.

Àkótán

Lótìítọ́ ni pé àwọn èròjà ìwòsàn wà lára èpo igi kaṣú. Ṣùgbọ́n, ìwádìí wa ṣàfihàn pé kò sí àbájáde sáyẹ́nsì kankan tó fí ìdí múlè pé èèpo ẹ̀yìn igi kaṣú le è pa oró ejò. Bákanáà ni kò sí àjọ tó ti fi òǹtẹ̀ lùú fún ìwòsàn.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »