YorubaEconomyFact Check

Ṣe lootọ ni Adeleke ti pari ilé iṣẹ́ amúnáwá tí iye rẹ̀ jẹ́ bilionu meji dọ́là?

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Olumulo ikanni ibaraenisore Facebook so wipe arakunrin Adedeji Adeleke ti kọ lakọ pari ileeṣẹ amunawa re kan ti iye re to bilionu meji owo dọ́là.

Ṣe lootọ ni Adeleke ti pari ilé iṣẹ́ amúnáwá tí iye rẹ̀ jẹ́ bilionu meji dọ́là?

Abajade iwadii: Irọ ni. Kò sí ojulowo iroyin to ṣ’atilẹyin ahesọ naa. Koda, ileeṣẹ Pacific Holdings, ti ogbeni Adeleke je oludari rẹ̀, kò fi iroyin kankan si ita lori akopari ileeṣẹ amunawa naa.

Ekunrere alaye

Isoro iná mọ̀nàmọ̀nà ti n ba orileede Naijiria finra fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, paapaa lori oro owo ati ki awon kan ni, ki awon miran ma ni.

Biotilejepe, opo agbara orileede Naijiria le pèse agbara ní ọnà egberun metala, sugbon egberun meta sí egberun marun lasan ni o n pèsè lọwọlọwọ fún aráàlú. Eyi sì máa ń ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn idiwọn kọọkan.

Olumulo kan lori ikanni Facebook, Pulse Trendz, sọ wípé ogbeni Adedeji Adeleke, eni tiise baba David Adeleke, ogbontarigi olorin, ti gbogbo ayé mọ sì Davido, tí parii ileeṣẹ amunawa tí iye rẹ̀ to bílíọ̀nù meji owo dọ́là. Olumulo náà fi kun pe ileeṣẹ amunawa naa a bèrè síí pèse ina fún àwon èèyàn mílíọ̀nù mẹta tí ọwọ rẹ kò si ni pọ̀ tó ti awọn ileeṣẹ amunawa tí a n lọ lọwọlọwọ.

Olumulo kan, Opeyemi Apejua fí didun inu rẹ̀ hàn pé, “Adupe lowo olorun fún àwon àgbààgbà bíi Baba Adeleke ati ọba Dáfídì (Davido).”

Won ṣ’atunpin ahesọ naa s’orí Facebook, YouTube àti TikTok.

Nitori pataki ọrọ́ naa si ọrọ ajé orile-ede ati atotonu awon eniyan, DUBAWA ṣe ìwádìí.

Ifidiododomule

A se itopinpin kókó ọrọ lórí ayelujara, ṣugbọn ojúlówó iwe iroyin kankan ò gbe ìròyìn nipa akọpari ileeṣẹ amunawa ọ̀ún. A ri iroyin kan nibi ti ọgbẹni Adeleke ti kede pe òun n ṣiṣẹ́ lori ileeṣẹ amunawa ti yoo tobi julo ni orileede Naijiria, iṣẹ́ naa a si pari ni oṣù kini ọdún 2025.

“Mo ti bere sii sise lori ileeṣẹ amunawa ti yoo tobu julo ni orileede Naijiria, titi osu kini odun 2025, iṣẹ́ ti ma pari lori ileeṣẹ naa,” arakunrin Adedeji lo sọ eyi.

Ṣùgbọ́n, ko si ikede kankan to fihan pe won ti kọ ileeṣẹ amunawa naa pari.

Koda, a kọ iwe ranse si ileeṣẹ Pacific Holdings lori ẹ̀rọ telifoonu, sugbon wọn kò fèsì.

Akotan

Biotilẹjẹpe arakunrin Adeleke kede pe oun kọ ileeṣẹ amunawa ti yoo tobi julọ lorileede Naijiria, ko si iroyin kankan to fi mule pe ise ti pari.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »