Yoruba

Òye àtọwọ́dá ni wọn fi ṣ’ẹda àwọn fọnran akalekako ori ikanni TikTok wọnyi ti o ṣ’eleri owó iranwọ

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: Àwọn fonran kan gbode kan lori ikanni TikTok, ede abinibi Hausa ati Yoruba ni wọn fi se, àwọn eniyan ti o n soro nibe seleri owo iranwo fun àwọn olumulo ikanni naa ti won ba te àwọn linki kookan. 

Ekunrere alaye

Ọrọ ajé orileede Naijiria ti mu ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ araalu f’aragba iṣe àwọn onijibiti. Iṣẹ́ kekere, owó nla ni àwọn ọ̀dọ́ n wa l’órí ayelujara.

Lootọ, ojulowo ise wa ni ori ayelujara, ti o nilo ìmọ̀ ati wákàtí melokan, ṣugbọn ebu lo po ju lori àwọn ẹ̀rọ alatagba wonyi. 

Bi ọrọ aje Naijiria se mẹhẹ ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ araalu si n kerora, akosile iwe iroyin Business Day yi fihan pe ko to ipin kan araalu ti o n gba to milionu kan naira gegebi owo osu. 

Àwọn nkan wọnyi jẹ edun ọkàn fun àwọn ojogbon ati amoye ni orileede Naijiria, sugbon ibe lati ri àwọn kan ti won ronu bi won a se lu enikeji ni jibiti.

Laipe yii, a ri àwọn fonran kan lori ikanni TikTok ti o gba àwọn eyan niyanju ki won tele linki kan ki won le f’orukọsilẹ. A s’akiyesi pe eni ti o n s’ọ̀rọ̀ ninu fonran naa n sọrọ ni ede abinibi, ki olumulo ma ṣe fura, ki wọn si le ro wipe o je ojulowo.

DUBAWA s’alabapade àwọn fonran kan ni ede Hausa ati Yoruba ti won s’eleri owó iranwo fun enikeni t’o ba f’orukọsilẹ amọṣa won gbodo te àwọn linki kookan ki won le forukosile. 

Òye àtọwọ́dá ni wọn fi ṣ’ẹda àwọn fọnran akalekako ori ikanni TikTok wọnyi ti o ṣ’eleri owó iranwọ

Aworan ti a ya lati irufe fonran ọ̀ún

A tun ri fonran kan ti o farajọ ipolongo ile ifowopamọ kan ni orileede Naijiria pe won ni ipese fun araalu ki won le ni anfaani lati gba àwìn owó lati banki ọ̀ún, ti won ba le fi orúkọ, banki ti won lo, ati nọmba wọn sílẹ̀. 

Òye àtọwọ́dá ni wọn fi ṣ’ẹda àwọn fọnran akalekako ori ikanni TikTok wọnyi ti o ṣ’eleri owó iranwọ

Aworan ipolongo naa

DUBAWA s’akiyesi pe àwọn olumulo t’ó ri fonran naa bẹrẹ sii kọ oruko, nọmba ati banki ti wọn lo sílẹ̀, ni ireti pe won a le gba owó. 

Òye àtọwọ́dá ni wọn fi ṣ’ẹda àwọn fọnran akalekako ori ikanni TikTok wọnyi ti o ṣ’eleri owó iranwọ

Aworan akosile olumulo

Nitori pataki ọ̀rọ̀ naa ati wipe o ṣeéṣe ki àwọn oni jibiti lo iru fonran yii lati fi sise gbájúẹ̀, DUBAWA gbe iwadii yii jade. 

Itopinpin ododo

DUBAWA ṣ’akiyesi pe àwọn to fi fonran naa s’ita san’wo fun ikanni TikTok ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ eeyan ri fonran naa.

Nigba ti a tẹlẹ okan lara àwọn linki iforukosile, o gbe wa lọ aaye ayelujara ti olumulo a se idanimọ ara re bi okunrin tabi obinrin. Ni igba miran, won bere boya olumulo fẹ́ ba oyinbo s’ọrọ ki won si gba owó.

Òye àtọwọ́dá ni wọn fi ṣ’ẹda àwọn fọnran akalekako ori ikanni TikTok wọnyi ti o ṣ’eleri owó iranwọ

Aworan aaye ayelujara ti linki naa jasi

Nigba ti a tele linki keji yii, nise lo gbe wa lo aaye ayelujara kan t’o ṣ’alaye bi eeyan ṣe le ri iṣẹ́ si orileede Canada, UK, Germany ati beebeelọ. Awon linki miran bere orúkọ ati banki ti olumulo n lo. Ipese irufe nkan wonyi le ṣ’akoba fun eeyan.

Òye àtọwọ́dá ni wọn fi ṣ’ẹda àwọn fọnran akalekako ori ikanni TikTok wọnyi ti o ṣ’eleri owó iranwọ

Ni igba miran, àwọn ipolongo kookan a bere boya oluware fe gba owó lori ayelujara, ti a ba tele linki yii, a gbe wa lo aaye ti wọn o kọ nkankan si.

DUBAWA lo ẹrọ AIorNot ati Deepfake-o-meter ki a le ṣ’aridaju àwọn fonran yii. Lori okan ninu àwọn fọnran naa, wọn kọ VEO s’abe fọnran ọ̀ún, VEO si jẹ oun èlò kan ti won ma fi n ṣ’ẹda fonran nilana oye àtọwọ́dá. 

Bakan naa, ede enu ati ihuwasi àwọn eniyan inu fonran naa fihan pe ayederu fonran nii, oye àtọwọ́dá ni won fi se..

Òye àtọwọ́dá ni wọn fi ṣ’ẹda àwọn fọnran akalekako ori ikanni TikTok wọnyi ti o ṣ’eleri owó iranwọ

Aworan esi AI or Not

Akotan

Asinilona ni àwọn fonran akalekako ti o n ṣ’eleri owó iranwọ fun àwọn araalu, koda ori aaye ayelujara miran ni o maa n jasi. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »